البلد

تفسير سورة البلد

الترجمة اليورباوية

Yorùbá

الترجمة اليورباوية

ترجمة معاني القرآن الكريم للغة اليوربا ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني عام الطبعة 1432هـ .

﴿بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ لَا أُقْسِمُ بِهَٰذَا الْبَلَدِ﴾

Èmi (Allāhu) búra pẹ̀lú ìlú yìí.

﴿وَأَنْتَ حِلٌّ بِهَٰذَا الْبَلَدِ﴾

Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).

﴿وَوَالِدٍ وَمَا وَلَدَ﴾

(Mo tún) búra pẹ̀lú òbí àti ohun t’ó bí.

﴿لَقَدْ خَلَقْنَا الْإِنْسَانَ فِي كَبَدٍ﴾

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.

﴿أَيَحْسَبُ أَنْ لَنْ يَقْدِرَ عَلَيْهِ أَحَدٌ﴾

Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?

﴿يَقُولُ أَهْلَكْتُ مَالًا لُبَدًا﴾

Ó (sì) ń wí pé: "Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì s.a.w.)"

﴿أَيَحْسَبُ أَنْ لَمْ يَرَهُ أَحَدٌ﴾

Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?

﴿أَلَمْ نَجْعَلْ لَهُ عَيْنَيْنِ﴾

Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?

﴿وَلِسَانًا وَشَفَتَيْنِ﴾

Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?

﴿وَهَدَيْنَاهُ النَّجْدَيْنِ﴾

A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.

﴿فَلَا اقْتَحَمَ الْعَقَبَةَ﴾

Kò sì mú àkàbà ìgbàlà gùn!

﴿وَمَا أَدْرَاكَ مَا الْعَقَبَةُ﴾

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ àkàbà ìgbàlà?

﴿فَكُّ رَقَبَةٍ﴾

(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.

﴿أَوْ إِطْعَامٌ فِي يَوْمٍ ذِي مَسْغَبَةٍ﴾

Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.

﴿يَتِيمًا ذَا مَقْرَبَةٍ﴾

(Ó lè jẹ́) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,

﴿أَوْ مِسْكِينًا ذَا مَتْرَبَةٍ﴾

tàbí mẹ́kùnnú, ẹni ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

﴿ثُمَّ كَانَ مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا وَتَوَاصَوْا بِالصَّبْرِ وَتَوَاصَوْا بِالْمَرْحَمَةِ﴾

Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.

﴿أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْمَيْمَنَةِ﴾

Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.

﴿وَالَّذِينَ كَفَرُوا بِآيَاتِنَا هُمْ أَصْحَابُ الْمَشْأَمَةِ﴾

Àwọn t’ó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.

﴿عَلَيْهِمْ نَارٌ مُؤْصَدَةٌ﴾

A máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.

الترجمات والتفاسير لهذه السورة: