المدّثر

تفسير سورة المدّثر

الترجمة اليورباوية

Yorùbá

الترجمة اليورباوية

ترجمة معاني القرآن الكريم للغة اليوربا ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني عام الطبعة 1432هـ .

﴿بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ يَا أَيُّهَا الْمُدَّثِّرُ﴾

Ìwọ olùdaṣọbora.

﴿قُمْ فَأَنْذِرْ﴾

Dìde kí o ṣèkìlọ̀.

﴿وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ﴾

Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.

﴿وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ﴾

Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.

﴿وَالرُّجْزَ فَاهْجُرْ﴾

Òrìṣà ni kí o jìnnà sí.

﴿وَلَا تَمْنُنْ تَسْتَكْثِرُ﴾

Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.

﴿وَلِرَبِّكَ فَاصْبِرْ﴾

Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.

﴿فَإِذَا نُقِرَ فِي النَّاقُورِ﴾

Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,

﴿فَذَٰلِكَ يَوْمَئِذٍ يَوْمٌ عَسِيرٌ﴾

ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,

﴿عَلَى الْكَافِرِينَ غَيْرُ يَسِيرٍ﴾

tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.

﴿ذَرْنِي وَمَنْ خَلَقْتُ وَحِيدًا﴾

Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan.

﴿وَجَعَلْتُ لَهُ مَالًا مَمْدُودًا﴾

Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá

﴿وَبَنِينَ شُهُودًا﴾

àti àwọn ọmọkúnrin t’ó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.

﴿وَمَهَّدْتُ لَهُ تَمْهِيدًا﴾

Mo sì ṣe ayé nírọ̀rùn fún un gan-an.

﴿ثُمَّ يَطْمَعُ أَنْ أَزِيدَ﴾

Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.

﴿كَلَّا ۖ إِنَّهُ كَانَ لِآيَاتِنَا عَنِيدًا﴾

Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.

﴿سَأُرْهِقُهُ صَعُودًا﴾

Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná) .

﴿إِنَّهُ فَكَّرَ وَقَدَّرَ﴾

Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).

﴿فَقُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ﴾

Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.

﴿ثُمَّ قُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ﴾

Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.

﴿ثُمَّ نَظَرَ﴾

Lẹ́yìn náà, ó wò sùn.

﴿ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ﴾

Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.

﴿ثُمَّ أَدْبَرَ وَاسْتَكْبَرَ﴾

Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìn dà, ó sì ṣègbéraga.

﴿فَقَالَ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ يُؤْثَرُ﴾

Ó sì wí pé: "Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.

﴿إِنْ هَٰذَا إِلَّا قَوْلُ الْبَشَرِ﴾

Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara"

﴿سَأُصْلِيهِ سَقَرَ﴾

Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr.

﴿وَمَا أَدْرَاكَ مَا سَقَرُ﴾

Kí l’ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ iná Saƙọr?

﴿لَا تُبْقِي وَلَا تَذَرُ﴾

(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.

﴿لَوَّاحَةٌ لِلْبَشَرِ﴾

Ó máa jó awọ ara di dúdú.

﴿عَلَيْهَا تِسْعَةَ عَشَرَ﴾

(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.

﴿وَمَا جَعَلْنَا أَصْحَابَ النَّارِ إِلَّا مَلَائِكَةً ۙ وَمَا جَعَلْنَا عِدَّتَهُمْ إِلَّا فِتْنَةً لِلَّذِينَ كَفَرُوا لِيَسْتَيْقِنَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَيَزْدَادَ الَّذِينَ آمَنُوا إِيمَانًا ۙ وَلَا يَرْتَابَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ وَالْمُؤْمِنُونَ ۙ وَلِيَقُولَ الَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ وَالْكَافِرُونَ مَاذَا أَرَادَ اللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ اللَّهُ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي مَنْ يَشَاءُ ۚ وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ ۚ وَمَا هِيَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْبَشَرِ﴾

Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika.
Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo.
(Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: "Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?" Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ̀ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.

﴿كَلَّا وَالْقَمَرِ﴾

Ẹ gbọ́! Allāhu búra pẹ̀lú òṣùpá.

﴿وَاللَّيْلِ إِذْ أَدْبَرَ﴾

Ó tún búra pẹ̀lú alẹ́ nígbà tí ó bá lọ.

﴿وَالصُّبْحِ إِذَا أَسْفَرَ﴾

Ó tún búra pẹ̀lú òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́.

﴿إِنَّهَا لَإِحْدَى الْكُبَرِ﴾

Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) t’ó tóbi.

﴿نَذِيرًا لِلْبَشَرِ﴾

(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.

﴿لِمَنْ شَاءَ مِنْكُمْ أَنْ يَتَقَدَّمَ أَوْ يَتَأَخَّرَ﴾

Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn.

﴿كُلُّ نَفْسٍ بِمَا كَسَبَتْ رَهِينَةٌ﴾

Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun t’ó ṣe níṣẹ́.

﴿إِلَّا أَصْحَابَ الْيَمِينِ﴾

Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.

﴿فِي جَنَّاتٍ يَتَسَاءَلُونَ﴾

Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra

﴿عَنِ الْمُجْرِمِينَ﴾

nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:

﴿مَا سَلَكَكُمْ فِي سَقَرَ﴾

"Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?"

﴿قَالُوا لَمْ نَكُ مِنَ الْمُصَلِّينَ﴾

Wọn yóò wí pé: "Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.

﴿وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ الْمِسْكِينَ﴾

Àwa kò sì sí nínú àwọn t’ó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.

﴿وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ الْخَائِضِينَ﴾

Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.

﴿وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ الدِّينِ﴾

Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san nírọ́

﴿حَتَّىٰ أَتَانَا الْيَقِينُ﴾

títí ikú fi dé bá wa."

﴿فَمَا تَنْفَعُهُمْ شَفَاعَةُ الشَّافِعِينَ﴾

Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.

﴿فَمَا لَهُمْ عَنِ التَّذْكِرَةِ مُعْرِضِينَ﴾

Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí

﴿كَأَنَّهُمْ حُمُرٌ مُسْتَنْفِرَةٌ﴾

bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ t’ó ń sá lọ,

﴿فَرَّتْ مِنْ قَسْوَرَةٍ﴾

t’ó sá fún kìnìhún?

﴿بَلْ يُرِيدُ كُلُّ امْرِئٍ مِنْهُمْ أَنْ يُؤْتَىٰ صُحُفًا مُنَشَّرَةً﴾

Rárá, ńṣe ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).

﴿كَلَّا ۖ بَلْ لَا يَخَافُونَ الْآخِرَةَ﴾

Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.

﴿كَلَّا إِنَّهُ تَذْكِرَةٌ﴾

Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.

﴿فَمَنْ شَاءَ ذَكَرَهُ﴾

Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kó rántí rẹ̀.

﴿وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّا أَنْ يَشَاءَ اللَّهُ ۚ هُوَ أَهْلُ التَّقْوَىٰ وَأَهْلُ الْمَغْفِرَةِ﴾

Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì làforíjìn.

الترجمات والتفاسير لهذه السورة: