الجبار
الجَبْرُ في اللغة عكسُ الكسرِ، وهو التسويةُ، والإجبار القهر،...
Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà t’ó máa ṣẹlẹ̀
sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).
(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí idẹ t’ó yọ́,
ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
àti àwọn ẹbí rẹ̀ t’ó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
àti gbogbo ẹni t’ó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná t’ó ń jò fòfò).
(Iná) yó máa ké sí ẹni t’ó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
nítorí náà, ẹni kẹ́ni t’ó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùtayọ-ẹnu àlà;
àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
Nítorí náà, Èmi ń búra pẹ̀lú Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùn , dájúdájú Àwa ni Alágbára
láti lè fi àwọn t’ó dára jù wọ́n lọ pààrọ̀ wọn. Kò sì sí ẹni t’ó lè kó agara bá Wa.
Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.