الطارق

تفسير سورة الطارق

الترجمة اليورباوية

Yorùbá

الترجمة اليورباوية

ترجمة معاني القرآن الكريم للغة اليوربا ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني عام الطبعة 1432هـ .

﴿بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَٰنِ الرَّحِيمِ وَالسَّمَاءِ وَالطَّارِقِ﴾

(Allāhu) búra pẹ̀lú sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ.

﴿وَمَا أَدْرَاكَ مَا الطَّارِقُ﴾

Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun t’ó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?

﴿النَّجْمُ الثَّاقِبُ﴾

Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).

﴿إِنْ كُلُّ نَفْسٍ لَمَّا عَلَيْهَا حَافِظٌ﴾

Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).

﴿فَلْيَنْظُرِ الْإِنْسَانُ مِمَّ خُلِقَ﴾

Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.

﴿خُلِقَ مِنْ مَاءٍ دَافِقٍ﴾

Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi t’ó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.

﴿يَخْرُجُ مِنْ بَيْنِ الصُّلْبِ وَالتَّرَائِبِ﴾

Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.

﴿إِنَّهُ عَلَىٰ رَجْعِهِ لَقَادِرٌ﴾

Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀

﴿يَوْمَ تُبْلَى السَّرَائِرُ﴾

ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.

﴿فَمَا لَهُ مِنْ قُوَّةٍ وَلَا نَاصِرٍ﴾

Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.

﴿وَالسَّمَاءِ ذَاتِ الرَّجْعِ﴾

Allāhu búra pẹ̀lú sánmọ̀ t’ó ń rọ òjò ní ọdọọdún.

﴿وَالْأَرْضِ ذَاتِ الصَّدْعِ﴾

Ó tún búra pẹ̀lú ilẹ̀ t’ó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso).

﴿إِنَّهُ لَقَوْلٌ فَصْلٌ﴾

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).

﴿وَمَا هُوَ بِالْهَزْلِ﴾

Kì í sì ṣe àwàdà.

﴿إِنَّهُمْ يَكِيدُونَ كَيْدًا﴾

Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.

﴿وَأَكِيدُ كَيْدًا﴾

Èmi náà sì ń déte gan-an.

﴿فَمَهِّلِ الْكَافِرِينَ أَمْهِلْهُمْ رُوَيْدًا﴾

Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.

الترجمات والتفاسير لهذه السورة: